Otito Nipa Iku Pharaoh: Ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé tú àṣírí ìsìnkú ọba Fáráò ri Egypt

Awọn oku awọn Ọba Farao nilẹ Egypti ti wọn ṣe lọjọ pamọ lawọn onimọ ijinlẹ ti fi imọ ẹrọ igbalode se awari wọn bayii.

Awọn oku iselọjọ Amenhotep akọkọ to jọba laarin ọdun 1525 si 1504 BC ni wọn ri ni ibudo kan ni Deir el-Bahari logoje ọdun sẹyin ti wọn si fi imọ ẹrọ ṣe nkan si wọn lara.

Awọn akọsẹmọsẹ iwadi nnkan iṣẹmbaye ti da ara wọn lọwọ kọ lati mase ṣi oku naa lọna ati lee paa mọ ni aye to wa.

Dr Sahar Saleem, professor of radiology at Cairo University's Kasr Al-Ainy Faculty of Medicine, stands next to the mummy of Amenhotep I and a CT scanner
Àkọlé àwòrán,Dr Saleem says the scans of the body did not show any wounds or disfigurement due to disease

Ni bayii imọ ẹrọ Computed Tomography, (CT) scans ti wa ṣe afihan awọn iroyin kan nipa Farao naa ati asiko isinku rẹ.

Kílódé tí àwọn èèyàn ṣe ń gbé òkú pamọ̀ sílé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìlú yìí?

Kàyéèfì! Ọwọ́ tẹ òkú tó ń ká àwọn èèyàn mọ́lé, to sì ń jà wọ́n lólè dúkìá

Wo ibi tí wọ́n ti ń sun ẹran èèyàn jẹ bí ẹran ìgbẹ́ tí ọwọ́ àjọ DSS tẹ èèyàn 30 lára wọnhttps://www.bbc.com/ws/av-embeds/cps/yoruba/59815412/p09nbcl7/yoÀkọlé fídíò,

Ṣé ẹ ti gbọ́ nípa òkú gbígbẹ́ tí wọ́n ṣì bá oyún nínú rẹ̀?

Omowe Sahar Saleem to jẹ ọjọgbọn imọ iwadi Radiology ni fasiti Cairo ṣalaye pe nipasẹ imọ ijinlẹ tuntun yii, wọn ti ṣe awari bi oju ọba naa ṣe ri lẹyin ẹgbẹrun ọdun mẹta to ku ti wọn si sinku rẹ.

Ọmọwe Saleem tun ṣalaye pe iyalẹnu ti awọn tun ri ni pe Ọba Amenhotep kini fi oju jọ baba rẹ Ahmose akọkọ to jẹ Farao akọkọ ninu itan ilẹ Egypti.

Iboju oku Amenhotep ti wọn gbe pamọ fun ọpọlọpọ ọdun

Awọn oluwadi ijinlẹ naa, ni awọn ti fi idi rẹ mulẹ pe iwọn bata marun un o le ni giga Amenhotep ati pe nnkan bii ẹni ọdun marundilogoji ni nigba to ku.

Saleem tun sọ pe ayẹwo igbalode naa fihan pe ṣaka lara rẹ da nigba iku rẹ ti ko si si ami ọgbẹ kankan lara rẹ tabi idibajẹ kankan nitori aisan tabi aarun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *