Opari : Ṣàǹgbá fọ́! Ìrètí Nàìjíríà fún góòlú, Adekuroye pòfo nínú ìjànkadì ní Tokyo 2020

Gbajugbaja ajijakandi, Odunayo Adekuroye ti ọpọ eeyan ti ni ireti pe oun ni yoo gba goolu fun Naijiria ninu idije Olympiki Tokyo 2020 fidi rẹmi lairo tẹlẹ.

Anastasia Nichita ọmọ orilẹ-ede Moldova lo fi iya jẹ Adekuroye niluu Tokyo.

Adekuroye lo kuku n kọkọ n ṣiwaju ninu ijankadi ọhun, koda ami ayo mẹjọ si meji ni Adekuroye fi n ṣagba Nichita.

Ṣadeedee kan ni nkan yi biri, ti Odunayo ṣubu loju ija.

Iṣubu yii gan an lo mu ki Nichita bori ninu ija ipele ẹlẹni mẹrindilogun ọhun

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *