Kafata Agbako Nla: Liverpool faṣọ iyì ya mọ́ Ole, Ronaldo àti Man U lára

Liverpool ṣe ẹgbẹ agbaboolu Manchester United risa-risa ninu Ifẹsẹwọnsẹ idije Premier League to waye ni papa isere Old Trafford lọjọ Aiku.
Àmì ayo marun ùn sodo ni Liverpool gba si awọn Man U nile wọn eleyii ti United ko sí lee ta putu.
Ẹlẹsẹ ayo n ni, Mohammed Salah lo gbayo mẹta ọtẹtọ wọlé fun Liverpool ninu ere bọọlu ọhún.
Naby Keita lo kökọ ṣide ayo nigba ti o gba góòlù akọkọ s’awọn Man United.
Diogo Jota lo fi ọba lee fun Liverpool ni Old Trafford.
Lẹyin naa ni agbaojẹ Salah gba góòlù mẹta lera s’awọn